UTME past questions
Yoruba / 2011 / 9
UTME Objective

AKAYE II

Bá a pọ̀sẹ̀sẹ̀ tà a kásàn.
Elédùà ló mẹnì óò rí dídùn ọsàn mu.
Ọ̀rẹ̀ rọra sarè ọlà.
Ò bá ṣe jẹ́jẹ.́
Ò bá fẹ̀sọ̀ lògbà.
Má fìkánjú ṣayé,
Má fi wàràwàrà mókùn ọlà.
Ìkánjú ò dà nǹkan fún'ni,
Ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ ló yẹ a lògbà.
Ẹni fi sùúrù pilẹ̀ ọrọ̀,
Irú wọn a fi rọ̀rùn lògbà.
Ìbàlẹ̀ ọkàn a filé wọn ṣebùgbé.
A-jẹ-n-gínńgín nií jẹ tájànàkú.
Ajẹwàrà a sì jẹ tẹ̀liírí
Ìgbẹ̀yìn ìkánjú àbámọ̀ níí dà
Ẹni kánjú ìwà a pòṣé,
Ẹni ó kánjú ọlà,
A bómi ọlà sàn lọ.
Ẹni fẹ̀lẹ̀ kó wà jọ a rẹ́rìn-ín.
Ẹni ó fẹ̀lẹ̀ kọ́là jọ
A rómi ọlà bù lámù.
Ìkánjú ohun pẹ̀lẹ́ ọ̀gbà ni.
Wọ́lá níba ọ̀rẹ́,
Fẹ̀lẹ̀ wọ́rọ̀.
Nitori ìkanjú wáyé,
Òun nìkánjú rọ̀run.
Má ṣe gbàgbé páyé labọ́lá,
Ayé náà la o fiílẹ̀ sí.
Àwọn olówó àná ńkọ́?
Wọ́n ti lọ̀ọ́ ràwo ẹṣin.
Ọ̀ rẹ,́ ẹ̀sọ̀ pèlẹ́ layé gbà.


Ìmọ̀ràn akéwì yìí ni pé kí á máa
A
sáré ká ikàn
B
dẹjú ká lè rímú
C
rọra jákùn ọlÃÂ
D
tètè ká ọsàn.
Answer:C
Practice more with TestDriller

To see detailed solution to this question and thousands of other questions offline, download TestDriller UTME. Practice rigorously for UTME, learn from video and text materials, enjoy educational games, summary of JAMB literature books, compete with your peers, win prizes and more.

Get TestDriller