UTME past questions
Yoruba / 2011 / 5
UTME Objective

Ka àwọn àyọkà yìí, kí o sì dàhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé wọn.
AKAYE I
Ò jẹ́ àṣà agbo ilé Arógundádé láti ṣe orò fún ọmọ tuntun kí wọ́n sì wo
àkọṣ̀jayé rẹ̀. Èyí ni wọ́n ṣe nígbà tí Alárápé àti Àdùnní bí Kọ́ládé. Àwòyè náà
ló ṣe é fún wọn ní ọjọ́ kẹjọ. Ó sọ ohun gbogbo nípa ọmọ tuntun yìí; ó
ṣàlàyé pé bí ó bá tó ọmọ ọdún méjìdínlógún kí àwọn òbí rẹ̀ ṣe ètùtù kan kí
ọ̀nà ìgbáyé rẹ̀ lè rọrùn.
Lẹ́yìn ọdún méje ni Alárápé àti aya rẹ̀ gbìyànjú ajé lọ ìlú Adégún,
Olódùmarè sì bùkún wọn níbẹ̀. Wọ́n rán Kọ́ládé ní ilé-ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí ojúṣe
wọn. Wọ́n fi ohun gbogbo tẹ́ ẹ lọ́rùn nítorí pé ó pọ̀ lọ́wọ́ wọn.
Lẹ́yìn tí Kọ́ládé kàwé gboyè, tó sì parí ìsinrú ìlú ni ó rí iṣẹ́ ìrọ̀rùn.
Ní àkókò yìí, Kọ́ládé ti di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Àwọn òbí rẹ̀ retí
kó mú aya wá ṣùgbọ́n ibi wọ́n fojú sí ọ̀nà kò gba bẹ̀. Nígbà tí ìrètí wọn fẹ́
máa pẹ́ jù, wọ́n fi ọ̀rọ̀ tó Àjọkẹ́ tí í ṣe ìbátan ìyá Kọ́ládé létí torí pé ojú ń kán
wọn láti rí ọmọ-ọmọ wọn. Àjọkẹ́ bá Rẹ́nikẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Kọ́ládé, ó sì fi ojú
àwọn méjèèjì kanra wọn.
Bí eré bí àwàdà ọ̀rọ̀ wọ̀ láàrin àwọn mẹ́jèèjì. Láì fọ̀rọ̀ gùn, àwọn ẹbí
méjèèjì ṣe ìdána, wọ́n sì mú ọjọ́ ìyàwo. Ìgbéyàwó náà yẹ wọ́n púpọ̀ ṣùgbọ́n
èso ìgbéyàwó kò tètè yọ.
Lẹ́yìn ọdún méjì ni wọ́n tó ṣalábàápàdé Awogba. Bàbá yìí ni ó sọ fún
wọn pe àìṣe ètùtù támòye kan sọ fún wọn lójọ́ pípẹ́ ṣẹ́yìn ní ó fa àìrọ́mọ bí.
Wàrà ǹ ṣe ṣà, gbogbo ohun ètùtù tí bàbá kà ni wọ́n wá. Ojú oórì ibi Kọ́ládé
ni wọ́n parí ètò gbogbo sí. Oṣù méjì lẹ́yìn akitiyan yìí ni Rẹ́nikẹ́ finú ṣoyún,
lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án, ẹkún ayọ̀ sọ lọ́ọ̀dẹ̀ Kọ́ládé. Ìbejì, takọ tabo ni Ẹlẹ́dàá fi
ta wọn lọ́rẹ. Inú Alárápé àti aya rẹ̀ dùn nítorí pé wọ́n ti sọ ìrètí nù láti gbé
ọmọ-ọmọ wọn láyé.


Ẹni tí ó dúró gégẹ́ bí alárinà láàrin Rénikẹ́ àti Kọ́ládé ni
A
Àdùnní
B
Àwòyè
C
Àjọkẹ́
D
Awogba.
Answer:C
Practice more with TestDriller

To see detailed solution to this question and thousands of other questions offline, download TestDriller UTME. Practice rigorously for UTME, learn from video and text materials, enjoy educational games, summary of JAMB literature books, compete with your peers, win prizes and more.

Get TestDriller